Entertainment

Reminisce Radio O-Y-O

Published

on


Radio O-Y-O in those days before FM Radios Stations Came to “Dabarued” Everything. Very Educative and Entertained.

Ibadan Used To Be Centre Of Activities In The Whole Of South West.

Some Educative And Instructive Jingles Back then…..

 

(1). Campaign Against Examination Malpractice

Lead: Àsírí ìkokò kò ye kó towó ajá tú ú

Chorus: E e in

Lead: Àsírí ìdánwò kò ye kó tenu re jáde

Chorus: E e in

Lead: Eni a fèyìn tì bí ó ba yè wíwí ní í wí

Chorus: E e in

Lead: Ó dífá fún gbogbo èyin tí a fèyìn tì ní I àsírí ìdánwò o

Choru: E e in

Lead: Ìwo olùkó, ìwo akòwè, ìwo atèwé

Má fàsírí ìdánwò han omo re

Má fàsírí ìdánwò han olùfé

Má fàsírí ìdánwò han nítorí owó

All: A kì ì mà mà í se rú è kó mó hun ni

A kì ì mà mà í se rú è kó mó hun ni o.

A kì ì mà mà mà í se ru è kómó hun ni!

Read also

Children’s day: Prof Adedibu urges children to shun cultism, hooliganism and robbery.

LIST OF THE 18 RADIO STATIONS IN OSUN STATE

(2)

For dignity in labour

Isé eni ni sé eni

Mó tijú isé re è

Ikán kì í tijú à á molé

Èèrà kì í à á yènà

Alápàńdèdè kì í tijú à ń fò kiri níta gbangba

Mó tijú isé re è

Ò bá à sàgbè, ò bá à sakòwé

Bó o jóní nàájà

Bó o jóní wóróbo

Mó tijú isé re è

Isé kì í pani àìse rè gan làbùkù!

 

(3)

Against theft and Pick Pocketer

Mo rí o o

Ìwo tó ñtowó bàpò alápò

Káì olè ni ò!

 

(4)

Eating varieties of food

Friend: Bàbá à Bólá (Bola Father) mo débí lánàá èbà lè ńje

Lónì yìí kan ná hàn èbà letún ńje

Háhà á kín lódé, èyin ò lóńje mí ìn ni?

Bàbá Bólá’s response: Òré mi ìwo ló tún so báyìí

Ká tó rí gaàrí òhún rà ńkó?

Friend: Ó tì o!

Isu ńbe lójà

Ìresì ńbe

Èlùbó nbe, àgbàdo ńbe

Dòdò àti dùūndú kìí mó ò soúnje alákòwé nì kan àn

Gbogbo rè ló dá a láa!

 

(5)

Household security at night

É Fura o, ìfura lòògùn àgbà

E fura!

Páńsá ò fura

Páńsá jáná

Àjà ò fura àjà jìn

Bó nílé ò bá fura

Olè ní ó kó lo

Té e bá fé sùn lálé

E tan ná yílé po

E sì tún tìlèkùn gboningbonin

E tójú u dúkìyà

Ká mó bá à fara wa lólè lówó.

 

(6)

Road safety and campaign against over speeding

Iná piti!

Gbé e n’lè

Tè é kanlè já wáyà è

Eesin je táyà e

Fún un ná à

Háhà kí ló dé ìwo ìyá yìí!

Háhà onímótò o ò sì sóra

Kinní kan mò ńbe léyìn nkàn àn

Dandan lowo ori je, tulasi laso ibora.

OwoorilafikoMapo…………

 

English jingles

Attention please! Attention please! Calling all drivers!Calling all drivers! Calling all motor scooter drivers! Excessive speeding can kill, have consideration for other road users’; a sweet rendition byYanjuAdegbite and there will be added music; ‘Aringbereniyomoyedele, asaretetekonimoyekan je’- That is, to be late is better than the late.

  • Avoid dirty and unripe fruits.
  • Cocaine is a killer.
  • Becareful with fire.
  • Don’t waste water.
  • Don’t jump the queue.
  • Don’t park your car just anywhere.

And some many other English jingles:

‘Sleeping on duty?’

‘Sorry sir!sorry sir!’

‘Sorry for yourself, you mustn’t have anaira added to your pay’


Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Trending

Exit mobile version